Sefanáyà 3:1-20
3 Ìlú tó ń ṣọ̀tẹ̀ gbé! Ó ti di ẹlẹ́gbin, ó sì ń ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára.+
2 Kò ṣègbọràn;+ kò gba ìbáwí.+
Kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+ kò sì sún mọ́ Ọlọ́run rẹ̀.+
3 Àwọn olórí tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tó ń ké ramúramù.+
Àwọn onídàájọ́ rẹ̀ jẹ́ ìkookò ní alẹ́;Wọn kì í jẹ egungun kankan kù di òwúrọ̀.
4 Aláfojúdi ni àwọn wòlíì rẹ̀, oníbékebèke ni wọ́n.+
Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń sọ ohun mímọ́ di ẹlẹ́gbin;+Wọ́n ń rú òfin.+
5 Jèhófà jẹ́ olódodo ní àárín rẹ̀;+ kò ní ṣe àìtọ́.
Àràárọ̀ ló ń jẹ́ ká mọ ìdájọ́ rẹ̀,+Kì í yẹ̀ bí ojúmọ́ kì í ti í yẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn aláìṣòdodo kò ní ìtìjú.+
6 “Mo pa àwọn orílẹ̀-èdè run; àwọn ilé gogoro tó wà ní àwọn ìkángun odi wọn ti di ahoro.
Mo pa àwọn ojú ọ̀nà wọn run, tí kò fi sí ẹni tó ń gbà á kọjá.
Àwọn ìlú wọn ti di àwókù tí kò sí ẹnì kankan níbẹ̀, tí kò sì ní olùgbé kankan.+
7 Mo sọ pé, ‘Dájúdájú, wàá bẹ̀rù mi, wàá sì gba ìbáwí,’*+Kí ibùgbé rẹ̀ má bàa pa run+Màá pè é wá jíhìn* nítorí gbogbo nǹkan yìí.
Síbẹ̀, ara túbọ̀ ń yá wọn láti hùwàkiwà.+
8 ‘Nítorí náà, ẹ máa retí mi,’*+ ni Jèhófà wí,‘Títí di ọjọ́ tí màá wá gba* ohun tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn,Nítorí ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, kí n sì kó àwọn ìjọba jọ,Kí n lè da ìrunú mi sórí wọn, gbogbo ìbínú mi tó ń jó fòfò;+Torí ìtara mi tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run.+
9 Nígbà náà, màá yí èdè àwọn èèyàn pa dà sí èdè mímọ́,Kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà,Kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìṣọ̀kan.’*+
10 Láti agbègbè àwọn odò tó wà ní Etiópíà,Ni àwọn tó ń pàrọwà sí mi, ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi tí wọ́n tú ká, ti máa mú ẹ̀bùn wá fún mi.+
11 Ní ọjọ́ yẹn, ojú ò ní tì ọ́Nítorí gbogbo ohun tí o ṣe láti fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi,+Torí nígbà náà, màá mú àwọn agbéraga tó ń fọ́nnu kúrò láàárín rẹ;O ò sì ní gbéra ga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.+
12 Màá jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti àwọn aláìní wà ní àárín rẹ,+Wọ́n á sì fi orúkọ Jèhófà ṣe ibi ààbò.
13 Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì+ kò ní hùwà àìṣòdodo;+Wọn kò ní parọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní fi ahọ́n wọn tanni jẹ;Wọ́n á jẹun,* wọ́n á sì dùbúlẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+
14 Kígbe ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì!
Kígbe ìṣẹ́gun, ìwọ Ísírẹ́lì!+
Máa yọ̀, sì jẹ́ kí ayọ̀ kún inú ọkàn rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù!+
15 Jèhófà ti mú àwọn ìdájọ́ kúrò lórí rẹ.+
Ó ti lé ọ̀tá rẹ dà nù.+
Ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà, wà ní àárín rẹ.+
Ìwọ kò ní bẹ̀rù àjálù mọ́.+
16 Ní ọjọ́ yẹn, a ó sọ fún Jerúsálẹ́mù pé:
“Má bẹ̀rù, ìwọ Síónì.+
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ domi.*
17 Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ.+
Ó máa gbani là bí Alágbára ńlá.
Ó máa yọ̀ gidigidi nítorí rẹ.+
Á dákẹ́ jẹ́ẹ́* nínú ìfẹ́ rẹ̀.
Á dunnú nítorí rẹ pẹ̀lú igbe ayọ̀.
18 Àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá torí pé wọn ò wá sí àwọn àjọyọ̀ rẹ ni màá kó jọ;+Wọn ò sí lọ́dọ̀ rẹ torí pé wọ́n wà ní ìgbèkùn, níbi tí wọ́n ti ń kẹ́gàn wọn.+
19 Wò ó! Ní àkókò yẹn, màá dojú ìjà kọ gbogbo àwọn tó ń pọ́n ọ lójú;+Màá gba ẹni tó ń tiro là,+Màá sì kó àwọn tó ti fọ́n ká jọ.+
Màá sọ wọ́n di ẹni iyì àti olókìkí*
Ní gbogbo ilẹ̀ tí ìtìjú ti bá wọn.
20 Ní àkókò yẹn, màá mú yín wọlé,Ní àkókò tí mo kó yín jọ.
Nítorí màá sọ yín di olókìkí* àti ẹni iyì+ láàárín gbogbo aráyé,Tí mo bá kó àwọn èèyàn yín tó wà ní oko ẹrú pa dà lójú yín,” ni Jèhófà wí.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “jìyà.”
^ Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”
^ Tàbí “fi sùúrù dúró dè mí.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ṣe ẹlẹ́rìí sí.”
^ Ní Héb., “ní èjìká kan.”
^ Tàbí “jẹko.”
^ Ní Héb., “kí ọwọ́ rẹ wálẹ̀.”
^ Tàbí “fọkàn balẹ̀; ní ìtẹ́lọ́rùn.”
^ Ní Héb., “orúkọ kan.”
^ Ní Héb., “orúkọ kan.”