Sekaráyà 10:1-12
10 “Ẹ bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí òjò rọ̀ ní àsìkò ìrúwé.
Jèhófà ló ń mú kí òjò ṣú dẹ̀dẹ̀,Òun ló ń rọ òjò fún wọn,+Òun ló sì ń fún gbogbo èèyàn ní ewéko.
2 Torí àwọn ère tẹ́ráfímù* ti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn;*Àwọn woṣẹ́woṣẹ́ sì ti rí ìran èké.
Àlá tí kò ní láárí ni wọ́n ń rọ́,Lásán sì ni wọ́n ń gbìyànjú láti tu àwọn èèyàn nínú.
Ìdí nìyẹn tí wọ́n á fi rìn gbéregbère bí àgùntàn.
Wọ́n á jìyà torí kò sí olùṣọ́ àgùntàn.
3 Inú bí mi gan-an sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn,Èmi yóò sì mú kí àwọn aṣáájú tó ń ni àwọn èèyàn lára* jíhìn;Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti yíjú sí agbo rẹ̀,+ sí ilé Júdà,Ó sì mú kí wọ́n dà bí ẹṣin rẹ̀ tó gbayì tó fi ń jagun.
4 Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni olórí* ti wá,Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni alákòóso tó ń tini lẹ́yìn* ti wá,Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ọfà tí wọ́n fi ń jagun ti wá;Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo alábòójútó,* ti jáde lọ, gbogbo wọn pátá.
5 Wọn yóò dà bí àwọn jagunjagun,Tó ń tẹ ẹrọ̀fọ̀ ojú ọ̀nà mọ́lẹ̀ lójú ogun.
Wọ́n á jagun torí Jèhófà wà pẹ̀lú wọn;+Ojú yóò sì ti àwọn tó ń gun ẹṣin.+
6 Èmi yóò gbé ilé Júdà lékè,Èmi yóò sì gba ilé Jósẹ́fù là.+
Màá dá wọn pa dà,Torí èmi yóò ṣàánú wọn;+Wọn yóò sì dà bí ẹni tí mi ò ta nù rí;+Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn, màá sì dá wọn lóhùn.
7 Àwọn ti Éfúrémù yóò dà bíi jagunjagun tó lákíkanjú,Ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bíi pé wọ́n mu wáìnì.+
Àwọn ọmọ wọn á rí èyí, inú wọn á sì dùn;Ọkàn wọn máa yọ̀ torí Jèhófà.+
8 ‘Màá súfèé sí wọn, màá sì kó wọn jọ;Torí màá rà wọ́n pa dà,+ wọ́n á sì pọ̀ sí i,Wọ́n á sì máa pọ̀ sí i.
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fọ́n wọn ká bí irúgbìn sáàárín àwọn èèyàn,Wọ́n á rántí mi ní ọ̀nà jíjìn tí wọ́n wà;Wọn á pa dà lókun, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì pa dà.
10 Màá mú wọn pa dà wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,Màá sì kó wọn jọ láti Ásíríà;+Màá mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì+ àti Lẹ́bánónì,Kò sì ní sí àyè fún wọn.+
11 Yóò la òkun kọjá pẹ̀lú wàhálà;Yóò sì pa ìgbì òkun lẹ́nu mọ́;+Gbogbo ibú Náílì yóò gbẹ táútáú.
Ìgbéraga Ásíríà yóò rọlẹ̀,Ọ̀pá àṣẹ Íjíbítì yóò sì kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+
12 Èmi, Jèhófà, yóò gbé wọn lékè,+Wọn yóò sì máa rìn ní orúkọ mi,’+ ni Jèhófà wí.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; àwọn òrìṣà.”
^ Tàbí “sọ ohun abàmì; sọ ohun àdììtú.”
^ Ní Héb., “òbúkọ.”
^ Ní Héb., “ilé ìṣọ́ igun ilé,” ó ṣàpẹẹrẹ èèyàn pàtàkì; ìjòyè.
^ Ní Héb., “èèkàn,” ó ṣàpẹẹrẹ ẹni tó ń tini lẹ́yìn; alákòóso.
^ Tàbí “akóniṣiṣẹ́.”