Sekaráyà 12:1-14

  • Jèhófà yóò dáàbò bo Júdà àti Jerúsálẹ́mù (1-9)

    • Jerúsálẹ́mù yóò di “òkúta tó wúwo” (3)

  • Wọ́n ń pohùn réré ẹkún torí ẹni tí wọ́n gún (10-14)

12  Ìkéde: “Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Ísírẹ́lì,” Ọ̀rọ̀ Jèhófà, Ẹni tó na ọ̀run jáde,+Tó fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀,+Tó sì dá ẹ̀mí* sínú èèyàn.  “Èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di ife* tó ń mú kí gbogbo àwọn tó yí i ká ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; wọn yóò sì gbógun ti Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+  Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di òkúta tó wúwo* fún gbogbo èèyàn. Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá gbé e máa fara pa yánnayànna;+ gbogbo orílẹ̀-èdè ayé sì máa kóra jọ láti gbéjà kò ó.+  Jèhófà sọ pé, “Ní ọjọ́ yẹn, màá dẹ́rù ba gbogbo ẹṣin, màá sì mú kí orí ẹni tó ń gùn ún dà rú. Ojú mi yóò wà lára ilé Júdà, àmọ́ màá fọ́ ojú gbogbo ẹṣin àwọn èèyàn náà.  Àwọn séríkí* Júdà yóò sì sọ nínú ọkàn wọn pé, ‘Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ti fún wa lókun nípasẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.’+  Ní ọjọ́ yẹn, màá ṣe àwọn séríkí Júdà bí ìkòkò iná láàárín igi àti bí ògùṣọ̀ oníná láàárín ìtí ọkà+ tí wọ́n tò jọ, wọn yóò sì jó gbogbo èèyàn tó wà yí ká run ní ọ̀tún àti ní òsì;+ àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù yóò sì pa dà sí àyè wọn,* ní Jerúsálẹ́mù.+  “Jèhófà yóò kọ́kọ́ gba àgọ́ Júdà là, kí iyì* ilé Dáfídì àti iyì* àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù má bàa pọ̀ gan-an ju ti Júdà lọ.  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù;+ ní ọjọ́ yẹn, ẹni tó bá kọsẹ̀* nínú wọn yóò dà bíi Dáfídì, ilé Dáfídì yóò sì dà bí Ọlọ́run, bí áńgẹ́lì Jèhófà tó ń lọ níwájú wọn.+  Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé màá pa gbogbo orílẹ̀-èdè tó wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù run.+ 10  “Màá tú ẹ̀mí ojú rere àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dáfídì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa wo ẹni tí wọ́n gún,+ wọ́n sì máa pohùn réré ẹkún torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń sunkún torí ọmọkùnrin kan ṣoṣo; wọ́n sì máa ṣọ̀fọ̀ gan-an torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ torí àkọ́bí ọmọkùnrin. 11  Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n á pohùn réré ẹkún gan-an ní Jerúsálẹ́mù, bí ẹkún tí wọ́n sun ní Hadadirímónì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+ 12  Ilẹ̀ náà máa pohùn réré ẹkún, ìdílé kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; ìdílé Nátánì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; 13  ìdílé Léfì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; ìdílé àwọn ọmọ Ṣíméì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; 14  àti gbogbo ìdílé tó ṣẹ́ kù, ìdílé kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “èémí.”
Tàbí “abọ́.”
Tàbí “òkúta tó jẹ́ ẹrù ìnira.”
Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.
Tàbí “àyè tó tọ́ sí wọn.”
Tàbí “ẹwà.”
Tàbí “ẹwà.”
Tàbí “ẹni tó jẹ́ aláìlera jù lọ.”