Sekaráyà 13:1-9

  • Ọlọ́run yóò mú àwọn òrìṣà àtàwọn wòlíì èké kúrò (1-6)

    • Ojú yóò ti àwọn wòlíì èké (4-6)

  • Wọ́n á kọ lu olùṣọ́ àgùntàn (7-9)

    • Ọlọ́run yóò yọ́ ìdá kẹta mọ́ (9)

13  “Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò gbẹ́ kànga kan fún ilé Dáfídì àti fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èérí wọn mọ́.+  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò pa orúkọ àwọn òrìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà,+ wọn ò sì ní rántí wọn mọ́; èmi yóò sì mú àwọn wòlíì+ àti ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ní ilẹ̀ náà.  Tí ọkùnrin kan bá tún ń sọ tẹ́lẹ̀, bàbá àti ìyá tó bí i yóò sọ fún un pé, ‘O ti fi orúkọ Jèhófà parọ́, o máa kú ni!’ Bàbá àti ìyá tó bí i yóò sì gún un pa torí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀.+  “Ní ọjọ́ yẹn, ojú yóò ti àwọn wòlíì nítorí ìran tí kálukú wọn ń rí nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; wọn ò sì ní wọ aṣọ onírun+ mọ́ láti tan àwọn èèyàn jẹ.  Yóò sì sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wòlíì. Àgbẹ̀ ni mí, torí ọkùnrin kan rà mí láti kékeré.’  Tí ẹnì kan bá sì bi í pé, ‘Ọgbẹ́ wo ló wà lára rẹ yìí?’* yóò dáhùn pé, ‘Ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi* ni mo ti fara gba ọgbẹ́.’”   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ìwọ idà, dìde sí olùṣọ́ àgùntàn mi,+Sí ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi. Kọ lu olùṣọ́ àgùntàn,+ kí agbo* sì tú ká;+Èmi yóò sì yí ọwọ́ mi pa dà sí àwọn tí kò já mọ́ nǹkan kan.”   Jèhófà sọ pé, “Ní gbogbo ilẹ̀ náà,Ìdá méjì nínú rẹ̀ yóò pa run, yóò sì ṣègbé;*Ìdá kẹta yóò sì ṣẹ́ kù síbẹ̀.   Èmi yóò fi ìdá kẹta sínú iná;Èmi yóò yọ́ wọn mọ́ bí wọ́n ṣe ń yọ́ fàdákà mọ́,Èmi yóò sì yẹ̀ wọ́n wò bí wọ́n ṣe ń yẹ wúrà wò.+ Wọ́n á ké pe orúkọ mi,Èmi yóò sì dá wọn lóhùn. Màá sọ pé, ‘Èèyàn mi ni wọ́n,’+ Wọ́n á sì sọ pé, ‘Jèhófà ni Ọlọ́run wa.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “láàárín ọwọ́ rẹ yìí?” Ìyẹn, ní àyà tàbí ẹ̀yìn.
Tàbí “àwọn tó fẹ́ràn mi.”
Tàbí “àgùntàn.”
Tàbí “kú.”