Sekaráyà 5:1-11

  • Ìran 6: Àkájọ ìwé tó ń fò (1-4)

  • Ìran 7: Agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà (5-11)

    • Obìnrin tó wà nínú rẹ̀ ń jẹ́ Ìwà Burúkú (8)

    • Wọ́n gbé agbọ̀n náà lọ sí ilẹ̀ Ṣínárì (9-11)

5  Mo tún wòkè, mo sì rí àkájọ ìwé kan tó ń fò.  Ó bi mí pé: “Kí lo rí?” Mo fèsì pé: “Mo rí àkájọ ìwé tó ń fò, tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́,* tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”  Ó wá sọ fún mi pé: “Èyí ni ègún tó ń lọ sí gbogbo ayé, bí wọ́n ṣe kọ ọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan ìwé náà, torí gbogbo ẹni tó ń jalè+ ti lọ láìjìyà; bí wọ́n sì ṣe kọ ọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kejì, torí gbogbo ẹni tó ń búra+ ti lọ láìjìyà.  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Mo ti rán an jáde, yóò sì wọnú ilé olè àti ilé ẹni tó ń fi orúkọ mi búra èké; yóò wà nínú ilé náà, yóò sì jẹ ẹ́ run, pẹ̀lú àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta rẹ̀.’”  Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ wá síwájú, ó sì sọ fún mi pé: “Jọ̀ọ́ wòkè, kí o sì wo ohun tó ń jáde lọ.”  Mo wá bi í pé: “Kí ni?” Ó fèsì pé: “Agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà* ló ń jáde lọ.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí wọ́n ṣe rí ní gbogbo ayé nìyẹn.”  Mo sì rí i tí wọ́n ṣí ìdérí roboto tí wọ́n fi òjé ṣe, obìnrin kan sì wà nínú agbọ̀n náà tó jókòó.  Áńgẹ́lì náà wá sọ pé: “Ìwà Burúkú nìyí.” Ó tì í pa dà sínú agbọ̀n náà, ó sì fi ìdérí tí wọ́n fi òjé ṣe náà dé e.  Lẹ́yìn náà, mo wòkè, mo sì rí obìnrin méjì tí wọ́n ń bọ̀, tí wọ́n ń yára fò nínú afẹ́fẹ́. Ìyẹ́ wọn dà bíi ti ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n sì gbé agbọ̀n náà kúrò nílẹ̀.* 10  Mo wá bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Ibo ni wọ́n ń gbé agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà yẹn lọ?” 11  Ó fèsì pé: “Ilẹ̀ Ṣínárì*+ ni wọ́n ń gbé e lọ, kí wọ́n lè kọ́lé fún obìnrin náà; tí wọ́n bá sì ti kọ́ ọ tán, wọn yóò fi í síbẹ̀, ní àyè rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ ṣẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “eéfà,” nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí ohun ìkó-nǹkan-sí tàbí apẹ̀rẹ̀ tó dọ́gba pẹ̀lú òṣùwọ̀n eéfà. Eéfà kan jẹ́ Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “Wọ́n sì gbé agbọ̀n náà sí àárín ayé àti ọ̀run.”
Ìyẹn, Babilóníà.