Sekaráyà 6:1-15
6 Mo tún wòkè, mo sì rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́rin tó ń bọ̀ láti àárín òkè méjì, òkè bàbà sì ni àwọn òkè náà.
2 Àwọn ẹṣin pupa ló ń fa kẹ̀kẹ́ àkọ́kọ́, àwọn ẹṣin dúdú ló sì ń fa kẹ̀kẹ́ kejì.+
3 Àwọn ẹṣin funfun ló ń fa kẹ̀kẹ́ kẹta, àwọn ẹṣin aláwọ̀ tó-tò-tó àti kàlákìnní ló sì ń fa kẹ̀kẹ́ kẹrin.+
4 Mo bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Kí làwọn nǹkan yìí, olúwa mi?”
5 Áńgẹ́lì náà dá mi lóhùn pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí+ mẹ́rin ti ọ̀run tó ń jáde lọ lẹ́yìn tí wọ́n dúró níwájú Olúwa gbogbo ayé.+
6 Èyí* tí àwọn ẹṣin dúdú ń fà jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá;+ èyí tí àwọn ẹṣin funfun ń fà lọ sí ìkọjá òkun; àwọn aláwọ̀ tó-tò-tó sì ń lọ sí ilẹ̀ gúúsù.
7 Ara sì ń yá àwọn ẹṣin aláwọ̀ kàlákìnní náà láti jáde lọ kí wọ́n lè rìn káàkiri ayé.” Áńgẹ́lì náà wá sọ pé: “Ẹ lọ, ẹ rìn káàkiri ayé.” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn káàkiri ayé.
8 Ó wá pè mí, ó sì sọ pé: “Wò ó, àwọn tó ń jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá ti rọ ẹ̀mí Jèhófà lójú ní ilẹ̀ náà.”
9 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
10 “Gba ohun tí Hélídáì, Tóbíjà àti Jedáyà mú wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn; ní ọjọ́ yẹn, kí ìwọ àti àwọn èèyàn yìí tó wá láti Bábílónì lọ sí ilé Jòsáyà ọmọ Sefanáyà.
11 Kí o fi fàdákà àti wúrà ṣe adé,* kí o sì fi dé orí Àlùfáà Àgbà Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì.
12 Kí o sì sọ fún un pé,“‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Èéhù+ rèé. Yóò hù jáde láti àyè rẹ̀, yóò sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà.+
13 Òun ni yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, òun ni iyì máa tọ́ sí. Yóò jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, yóò sì ṣàkóso, yóò sì tún jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ ọ̀kan kò sì ní pa èkejì lára.*
14 Adé* náà yóò jẹ́ ohun ìrántí fún Hélémù, Tóbíjà, Jedáyà+ àti Hénì ọmọ Sefanáyà nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà.
15 Àwọn tó wà lọ́nà jíjìn yóò wá, wọ́n sì máa wà lára àwọn tí yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà.” Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀, tí ẹ bá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, kẹ̀kẹ́ ẹṣin.
^ Tàbí “adé ńlá.”
^ Ìyẹn, ipò rẹ̀ bí alákòóso àti àlùfáà.
^ Tàbí “Adé ńlá.”