Sekaráyà 7:1-14

  • Jèhófà dẹ́bi fún àwọn tó ń gbààwẹ̀ tí kò dénú (1-14)

    • “Ṣé torí mi lẹ ṣe gbààwẹ̀ lóòótọ́?” (5)

    • ‘Ẹ dá ẹjọ́ òdodo, kí ìfẹ́ tí ẹ ní má yẹ̀, kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín’ (9)

7  Ní ọdún kẹrin tí Ọba Dáríúsì ti ń ṣàkóso, Jèhófà bá Sekaráyà+ sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án, ìyẹn oṣù Kísíléfì.*  Àwọn ará Bẹ́tẹ́lì rán Ṣárésà àti Regemu-mélékì àti àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè bẹ Jèhófà pé kó ṣojúure sí wọn,*  wọ́n ń sọ fún àwọn àlùfáà ilé* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun àti fún àwọn wòlíì pé: “Ṣé kí n sunkún ní oṣù karùn-ún,+ kí n má sì jẹun, bí mo ti ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún?”  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:  “Sọ fún gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà àti àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ gbààwẹ̀, tí ẹ sì pohùn réré ẹkún ní oṣù karùn-ún àti oṣù keje+ fún àádọ́rin (70) ọdún,+ ṣé torí mi lẹ ṣe gbààwẹ̀ lóòótọ́?  Nígbà tí ẹ jẹ tí ẹ sì mu, ṣebí torí ara yín lẹ ṣe ń jẹ tí ẹ sì ń mu?  Ṣé kò yẹ kí ẹ ṣe ohun tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́,+ nígbà tí àwọn èèyàn ń gbé ní Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú tó yí i ká, tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà àti nígbà tí àwọn èèyàn ń gbé ní Négébù àti Ṣẹ́fẹ́là?’”  Jèhófà tún sọ fún Sekaráyà pé:  “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ dá ẹjọ́ òdodo,+ kí ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín má yẹ̀,+ kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín. 10  Ẹ má lu opó tàbí ọmọ aláìníbaba* ní jìbìtì,+ ẹ má lu àjèjì tàbí aláìní ní jìbìtì,+ ẹ má sì gbèrò ibi sí ara yín nínú ọkàn yín.’+ 11  Àmọ́ wọn ò fetí sílẹ̀,+ agídí wọn mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi,+ wọ́n sì di etí wọn kí wọ́n má bàa gbọ́.+ 12  Wọ́n mú kí ọkàn wọn le bíi dáyámọ́ǹdì,*+ wọn ò sì tẹ̀ lé òfin* àti ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fi ẹ̀mí rẹ̀ sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́.+ Torí náà, inú bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun gan-an.”+ 13  “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Bí wọn ò ṣe fetí sílẹ̀ nígbà tí mo* pè wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ náà ni mi ò ní fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá pè.+ 14  Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn ò mọ̀.+ Ilẹ̀ náà di ahoro lẹ́yìn wọn, ẹnì kankan ò kọjá níbẹ̀, ẹnì kankan ò sì pa dà síbẹ̀;+ torí wọ́n ti sọ ilẹ̀ dáradára náà di ohun tó ń dẹ́rù bani.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tu Jèhófà lójú.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “ọmọ aláìlóbìí.”
Tàbí kó jẹ́, “òkúta líle,” irú bí òkúta émérì.
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ní Héb., “ó.”