Sí Títù 3:1-15

  • Ìtẹríba tí ó tọ́ (1-3)

  • Múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere (4-8)

  • Yẹra fún fífa ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání àti ẹ̀ya ìsìn (9-11)

  • Ìkíni àti ohun tó sọ fún Títù pé kí ó ṣe (12-15)

3  Máa rán wọn létí pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ, kí wọ́n máa ṣègbọràn sí wọn,+ kí wọ́n sì múra tán láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo,  kí wọ́n má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan láìdáa, kí wọ́n má ṣe jẹ́ oníjà, kí wọ́n máa fòye báni lò,+ kí wọ́n jẹ́ oníwà tútù sí gbogbo èèyàn.+  Nítorí nígbà kan rí, àwa náà jẹ́ aláìnírònú, aláìgbọràn, ẹni tí wọ́n ṣì lọ́nà, tó sọ ara rẹ̀ di ẹrú oríṣiríṣi ìfẹ́ ọkàn àti adùn, tó ń hu ìwà búburú tó sì ń ṣe ìlara, àwọn èèyàn kórìíra wa, a sì kórìíra ọmọnìkejì wa.  Àmọ́ nígbà tí Olùgbàlà wa Ọlọ́run, fi inú rere+ àti ìfẹ́ tó ní sí aráyé hàn,  (kì í ṣe torí iṣẹ́ òdodo kankan tí a ṣe,+ ṣùgbọ́n torí àánú rẹ̀),+ ó gbà wá là nípasẹ̀ ìwẹ̀ tó mú ká ní ìyè+ àti bó ṣe sọ wá di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+  Ó tú ẹ̀mí yìí sórí wa ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́* nípasẹ̀ Jésù Kristi Olùgbàlà wa,+  kó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ bá ti sọ wá di olódodo,+ a ó lè di ajogún+ ìyè àìnípẹ̀kun tí à ń retí.+  Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbára lé, mo sì fẹ́ kí o máa tẹnu mọ́ nǹkan wọ̀nyí, kí àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ lè máa ronú lórí ṣíṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo. Àwọn nǹkan yìí dára, wọ́n sì ń ṣeni láǹfààní.  Ṣùgbọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni fa ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání àti ọ̀rọ̀ ìtàn ìdílé, má sì dá sí ìjiyàn àti ìjà lórí Òfin, torí wọn kò lérè, wọn kò sì wúlò.+ 10  Tí ẹnì kan bá ń gbé ẹ̀ya ìsìn lárugẹ,+ tí o sì ti kìlọ̀ fún un* lẹ́ẹ̀kíní àti lẹ́ẹ̀kejì,+ ṣe ni kí o yẹra fún un,+ 11  torí o mọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kúrò lójú ọ̀nà, ó sì ń dẹ́ṣẹ̀, ìwà rẹ̀ sì ti dá a lẹ́jọ́. 12  Nígbà tí mo bá rán Átémásì tàbí Tíkíkù  + sí ọ, rí i pé o wá bá mi ní Nikopólísì, torí ibẹ̀ ni mo fẹ́ wà ní ìgbà òtútù. 13  Tún rí i pé o fún Sénásì, ẹni tó mọ Òfin dunjú àti Àpólò ní ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n má bàa ṣaláìní ohunkóhun lẹ́nu ìrìn àjò wọn.+ 14  Àmọ́, ó yẹ kí àwọn èèyàn wa tún kẹ́kọ̀ọ́ láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kí wọ́n lè máa ṣèrànwọ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá wáyé,+ kí wọ́n bàa lè máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní.*+ 15  Gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ mi kí ọ. Bá mi kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa tí a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “lọ́pọ̀lọpọ̀.”
Tàbí “bá a wí.”
Ní Grk., “má bàa di aláìléso.”