ÌBÉÈRÈ 2
Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ọlọ́run?
“Ìwé Òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á tọ̀sántòru, kí o lè rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀; ìgbà yẹn ni ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, tí wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.”
“Wọ́n ń ka ìwé náà sókè nìṣó látinú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, wọ́n sì ń túmọ̀ rẹ̀; torí náà, wọ́n jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lóye ohun tí wọ́n kà.”
“Aláyọ̀ ni ẹni tí kì í tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn èèyàn burúkú . . . , ṣùgbọ́n òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru. . . . Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.”
“Fílípì sáré lọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì gbọ́ tí ó ń ka ìwé wòlíì Àìsáyà sókè, ó wá bi í pé: ‘Ǹjẹ́ o tiẹ̀ lóye ohun tí ò ń kà?’ Ó dáhùn pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè lóye, láìjẹ́ pé ẹnì kan tọ́ mi sọ́nà?’”
“Nítorí àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá, títí kan agbára ayérayé tó ní àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run, tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre.”
“Máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí; jẹ́ kó gbà ọ́ lọ́kàn, kí gbogbo èèyàn lè rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú.”
“Ẹ . . . jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀.”
“Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì máa fún un, torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn tó bá ń fúnni.”