ÌBÉÈRÈ 1
Ta Ni Ọlọ́run?
“Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.”
“Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ló dá wa, tirẹ̀ la sì jẹ́.”
“Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn; èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì, èmi kì í sì í fi ìyìn mi fún àwọn ère gbígbẹ́.”
“Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò rí ìgbàlà.”
“Ó dájú pé, gbogbo ilé ló ní ẹni tó kọ́ ọ, àmọ́ Ọlọ́run ló kọ́ ohun gbogbo.”
“Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó. Ta ló dá àwọn nǹkan yìí? Òun ni Ẹni tó ń mú wọn jáde bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní iye-iye; Ó ń fi orúkọ pe gbogbo wọn. Torí okun rẹ̀ tó fi ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yanturu, agbára rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù, ìkankan nínú wọn ò di àwátì.”