ÌBÉÈRÈ 16
Kí Lo Lè Ṣe Tí Àníyàn Bá Ń Dà Ọ́ Láàmú?
“Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró. Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú láé.”
“Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere, àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.”
“Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́, ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.”
“Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?”
“Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”
“Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”
“Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”