Àwọn ará wà ní àpéjọ àgbáyé ti ọdún 2014 ní New Jersey, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI April 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Jí! àti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lọni. Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Rere Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ń Fúnni Lókun

Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta kò tù ú nínú, ń ṣe ni wọ́n tún dá kún ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Jóòbù tí wọ́n sì fi àwọn ẹ̀sùn èké kàn án. (Jóòbù 16-20)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ohun Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò

Máa fi ohun tuntun tá a pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ” bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jóòbù Kò Fàyè Gba Èrò Òdì

Wo ìyàtọ̀ tó wà nínú àwọn irọ́ tí Sátánì ń pa mọ́ Jèhófà àti bí ọ̀rọ̀ wa ṣe rí lára Jèhófà. (Jóòbù 21-27)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jóòbù Fi Àpẹẹrẹ Ìwà Títọ́ Lélẹ̀

Jóòbù pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà, ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà. (Jóòbù 28-32)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ Máa Ń Sọ Ọ̀rọ̀ Tó Gbéni Ró

Máa fi ìfẹ́ bá àwọn èèyàn lò bí Élíhù ṣe ṣe sí Jóòbù ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jóòbù 33-37)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

A Máa Pín Ìwé Ìkésíni sí Àpéjọ Àgbègbè

Àwọn nǹkan tó yẹ kó o fi sọ́kàn tó o bá ń pín ìwé ìkésíni sí àpéjọ àgbègbè. Fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí dánra wò.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

Ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o là gbà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn mí ì nígbà àpéjọ àgbègbè.