Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè

Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa ló ń darí wa nígbà gbogbo àti ní pàtàkì, nígbà àpéjọ àgbègbè. (Mt 22:37-39) Kọ́ríńtì Kìíní 13:4-8 sọ àwọn ohun tí ìfẹ́ máa ń ṣe, ó ní: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. . . . [Ìfẹ́] kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. . . . Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” Bí o ṣe ń wo fídíò náà Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè, ronú nípa onírúurú ọ̀nà tí wàá gbà fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè.

BÁWO LA ṢE LÈ FI HÀN PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ WA . . .

  • tá a bá ń gba àyè ìjókòó?

  • tí ohùn orin bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀?

  • tá a bá wà níbi tá a dé sí?

  • tá a bá ń yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni?