Àwọn ará ń kí arábìnrin kan káàbọ̀ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI April 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Jí! lọni àti láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Darí Èrò àti Ìṣe Rẹ

Amọ̀kòkò tó ga jù lọ náà ń mọ wá ká lè ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí, àmọ́ àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀

Gbogbo àwọn tó bá wá sí ìpàdé wa gbọ́dọ̀ rí i pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ ara wa. Báwo lo ṣe lè pa kún ìfẹ́ yìí nínú ìwà àti ìṣe rẹ?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ǹjẹ́ O Ní ‘Ọkàn-àyà Láti Mọ’ Jèhófà?

Ní Jeremáyà orí 24, Jèhófà Ọlọ́run fi àwọn èèyàn wé èso ọ̀pọ̀tọ́. Àwọn wo ló dà bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tó dáa, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn lónìí?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí

Àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣì ṣeyebíye lójú Jèhófà Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú ìjọ?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà

Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ogójì ọdún pé Jerúsálẹ́mù máa di ahoro. Kí ló ràn án lọ́wọ́ tó fi jẹ́ onígboya?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run Máa Ń Jẹ́ Ká Nígboyà

Orin Ìjọba Ọlọ́run tí àwọn ará wa ń kọ ló fún wọn lókun nígbà tí wọ́n wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Sachsenhausen. Àwọn orin yìí lè fún àwa náà nígboyà nígbà ìṣòro.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Májẹ̀mú Tuntun

Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín májẹ̀mú tuntun àti májẹ̀mú Òfin, ọ̀nà wo sì ni àwọn àǹfààní ibẹ̀ fi wà títí ayé?