Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 22-24

Ǹjẹ́ O Ní ‘Ọkàn-àyà Láti Mọ’ Jèhófà?

Ǹjẹ́ O Ní ‘Ọkàn-àyà Láti Mọ’ Jèhófà?

Jèhófà fi àwọn èèyàn wé èso ọ̀pọ̀tọ́

24:5

  • Àwọn olóòótọ́ lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì dà bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tó dára

24:8

  • Sedekáyà Ọba tó jẹ́ aláìṣòótọ́ àtàwọn míì tó hùwà búburú dà bí èso àjàrà tí kò dára

Báwo la ṣe lè ní ‘ọkàn-àyà láti mọ’ Jèhófà?

24:7

  • Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń fi ohun tá a kọ́ sílò, Jèhófà máa fún wa ní “ọkàn-àyà láti mọ̀” ọ́n

  • A gbọ́dọ̀ yẹ ọkàn wa wò dáadáa, ká sì mú àwọn ìwà tí kò dára àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kúrò níbẹ̀

Bi ara rẹ pé: Ǹjẹ́ mo ní ‘ọkàn-àyà láti mọ’ Jèhófà? Báwo ni mo ṣe lè ní “ọkàn-àyà láti mọ̀” ọ́n?