Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run Máa Ń Jẹ́ Ká Nígboyà

Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run Máa Ń Jẹ́ Ká Nígboyà

Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi orin yin Jèhófà nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n. (Iṣe 16:25) Bákan náà lóde òní, ńṣe ni àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Sachsenhausen lórílẹ̀-èdè Jámánì lábẹ́ ìjọba Násì àti nígbà tí wọ́n fi tipátipá kó àwọn ará wa kan lọ sígbèkùn ní Siberia. Àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé àwọn orin wa máa ń fún àwọn Kristẹni tó ń dojú kọ ìṣòro nígboyà.

Láìpẹ́, a máa ṣe ìwé orin wa tuntun náà, “Sing Out Joyfully” to Jehovah láwọn èdè púpọ̀ sí i. Tá a bá ti gba ìwé orin yìí, a lè mọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà sórí tá a bá ń kọ ọ́ nígbà ìjọsìn ìdílé wa. (Ef 5:19) Tí àdánwò bá dé, ẹ̀mí mímọ́ á rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà. Àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí ìrètí wa túbọ̀ dájú lọ́kàn wa. Wọ́n máa ń fún wa lókun nígbà ìṣòro. Tó bá sì jẹ́ pé inú wa ń dùn ni, àwọn ọ̀rọ̀ orin tó ń mọ́kàn yọ̀ tó wà níbẹ̀ máa ń jẹ́ ká lè máa ‘fi ayọ̀ kọrin sí Jèhófà’ torí pé inú wa ń dùn, ọkàn wa sì balẹ̀. (1Kr 15:16; Sm 33:1-3) Ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run!

WO FÍDÍÒ NÁÀ ORIN TÓ Ń RU ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ SÓKÈ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló mú kí Arákùnrin Frost ṣe orin kan fúnra rẹ̀?

  • Báwo ni orin yẹn ṣe fún àwọn arákùnrin tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen lókun?

  • Àwọn ìṣòro wo ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́, báwo sì ni àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run ṣe lè fún ọ lókun?

  • Àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run wo ló wù ẹ́ kó o mọ̀ sórí?