April 3- 9
JEREMÁYÀ 17-21
Orin 69 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Darí Èrò àti Ìṣe Rẹ”: (10 min.)
Jer 18:1-4
—Àrà tó bá wu amọ̀kòkò ló lè fi amọ̀ dá (w99 4/1 22 ¶3) Jer 18:5-10
—Jèhófà ní àṣẹ lórí àwa èèyàn (it-2 776 ¶4) Jer 18:11
—Jẹ́ amọ̀ tí ó rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà (w99 4/1 22 ¶4-5)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jer 17:9—Báwo la ṣe lè mọ̀ tí ọkàn ẹnì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àdàkàdekè? (w01 10/15 25 ¶13)
Jer 20:7
—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo okun rẹ̀ lórí Jeremáyà tó sì tàn án? (w07 3/15 9 ¶6) Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 21:3-14
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 118
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (5 min.) Ẹ tún lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 22)
“Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀”: (10 min.) Fi àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú-mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ apá yìí. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, Steve Gerdes: A Ò Lè Gbàgbé Ìkíni Yẹn Láyé.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 10 ¶12-19, àpótí “Wọ́n RÍ Ìlàlóye Gbà Ní ṢÍsẹ̀-n-tẹ̀lé Nípa Àgbélébùú,” àti àtúnyẹ̀wò “Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 5 àti Àdúrà