Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 17-21

Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Darí Èrò àti Ìṣe Rẹ

Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Darí Èrò àti Ìṣe Rẹ

Jẹ́ amọ̀ tí ó rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà

18:1-11

  • Jèhófà lè fi ìmọ̀ràn tàbí ìbáwí tọ́ wa sọ́nà ká lè ní àwọn ìwà tó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn

  • Bí amọ̀ tó rọ̀ ló ṣe yẹ ká rí lọ́wọ́ Jèhófà, ká sì jẹ́ onígbọràn

  • Jèhófà kì í fipá mú wa ṣe ohunkóhun

Àrà tó bá wu amọ̀kòkò ló lè fi amọ̀ dá

  • Torí pé Jèhófà ti fún wa lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá, a lè gbà kí ó mọ wá tàbí ká kọ̀ jálẹ̀

  • Ohun tá a bá ṣe nígbà tí Jèhófà bá ń tọ́ wa sọ́nà ló máa pinnu bí òun náà á ṣe máa ṣe sí wa

Àwọn apá wo nígbèésí ayé mi ló ti yẹ kí n jẹ́ kí Jèhófà mọ mí?