ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI April 2018
Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
Ìjíròrò tó dá lórí Bíbélì àti bá a ṣe lè láyọ̀.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ìyàtọ̀ àti Ìjọra Tó Wà Láàárín Ìrékọjá àti Ìrántí Ikú Kristi
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìrékọjá kò ṣàpẹẹrẹ Ìrántí Ikú Kristi, síbẹ̀ apá kan wà nínú rẹ̀ tó ní ìtumọ̀ pàtàkì fún wa.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ẹ Lọ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn—Kí Nìdí, Níbo àti Báwo?
Ká tó lè sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, a gbọ́dọ̀ kọ́ wọn láti máa pa àṣe Jésù mọ́. Lára ohun tá a máa ṣe ká tó lè sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ni pé ká kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa láti máa fi ẹ̀kọ́ Jésù sílò kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Iṣẹ́ Ìwàásù àti Kíkọ́ni Ṣe Pàtàkì Láti Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ, kí wọ́n sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Kí ni èyí gba pé kí wọ́n ṣe? Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ lọ́kàn wọn?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“A Dárí Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ Jì”
Kí la rí kọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu tó wà lákọsílẹ̀ nínú Máàkù 2:5-12? Báwo ni ìtàn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń ṣàìsàn?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jésù Ṣe Ìwòsàn ní Ọjọ́ Sábáàtì
Kí nìdí tí ìwà àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù fi kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jésù gidigidi? Àwọn ìbéèrè wo ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń fara wé àpẹẹrẹ àánú Jésù?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jésù Ní Agbára Láti Jí Àwọn Èèyàn Wa Tó Kú Dìde
A máa túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú àjíǹde tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, tá a bá ń ronú lórí àwọn àjíǹde tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Lo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́nà Tó Já Fáfá
Ká lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó múná dóko, a gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe lè lo àwọn ohun tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Kí ni olórí ohun èlò wa? Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọ àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ lò dáadáa?