Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

April 16-​22

MÁÀKÙ 1-2

April 16-​22
  • Orin 130 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • A Dárí Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ Jì”: (10 min.)

    • [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Máàkù.]

    • Mk 2:​3-5​—Àánú sún Jésù láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ọkùnrin arọ kan (jy 67 ¶3-5)

    • Mk 2:​6-12​—Bí Jésù ṣe wo ọkùnrin arọ yẹn sàn fi hàn pé ó ní àṣẹ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini (“Èwo ni ó rọrùn jù” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 2:9, nwtsty)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Mk 1:11​—Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jésù yìí túmọ̀ sí? (“ohùn kan sì wá láti inú àwọsánmà,” “Ìwọ ni Ọmọ mi,” “mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 1:11, nwtsty)

    • Mk 2:​27, 28​—Kí nìdí tí Jésù fi pe ara rẹ̀ ní “Olúwa . . . sábáàtì”? (“Olúwa . . . sábáàtì” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 2:28, nwtsty)

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mk 1:​1-15

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín.

  • Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.

  • Ìpadàbẹ̀wò Kejì​—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 44

  • “Èmi Kò Wá Láti Pe Àwọn Olódodo, Bí Kò Ṣe Àwọn Ẹlẹ́ṣẹ̀”: (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Mo Rìnnà Kore Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Báwo ni Donald ṣe yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù kì í ṣe é ṣojúsàájú tá a bá ń wàásù?​—Mk 2:17.

  • Jèhófà Máa Ń Dárí Jì “Lọ́nà Títóbi”: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Jèhófà, Ìwọ Ni Màá Fi Sípò Àkọ́kọ́ Nígbèésí Ayé Mi. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Báwo ni Anneliese ṣe pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí sì nìdí? (Ais 55:​6, 7) Báwo lo ṣe lè fi ìrírí yìí ran àwọn tó ti ń fi Jèhófà sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ lọ́wọ́?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 6 ¶10-15 àti àpótí “Irú Eré Ìnàjú Wo Ló Yẹ Kí N Yàn?

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 86 àti Àdúrà