April 2-8
MÁTÍÙ 26
Orin 19 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìyàtọ̀ àti Ìjọra Tó Wà Láàárín Ìrékọjá àti Ìrántí Ikú Kristi”: (10 min.)
Mt 26:17-20—Jésù jẹ Ìrékọjá tó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ (“Oúnjẹ Ìrékọjá” àwòrán àti fídíò lórí Mt 26:18, nwtsty)
Mt 26:26—Búrẹ́dì tá a máa ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ṣàpẹẹrẹ ara Jésù (“túmọ̀ sí” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:26, nwtsty)
Mt 26:27, 28—Wáìnì tá a máa ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi ṣàpẹẹrẹ “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” Jésù (“ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:28, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 26:17—Kí nìdí tí wọ́n fi pe Nísàn 13 ní “ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú”? (“Ní ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:17, nwtsty)
Mt 26:39—Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Jésù gbàdúrà pé: “Jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá”? (“jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:39, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 26:1-19
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 55 ¶21-22
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (8 min.)
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Ìràpadà: (7 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n pé: Kí nìdí tàwọn èèyàn fi ń ṣàìsàn, tí wọ́n ń darúgbó, tí wọ́n sì ń kú? Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe? Ta lo máa fẹ́ rí nínú Párádísè?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv àfikún “Kíkí Àsíá, Dídìbò àti Sísin Ìlú Ẹni”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 74 àti Àdúrà