April 30–May 6
MÁÀKÙ 5-6
Orin 151 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jésù Ní Agbára Láti Jí Àwọn Èèyàn Wa Tó Kú Dìde”: (10 min.)
Mk 5:38—Inú wa máa ń bà jẹ́ tí èèyàn wa bá kú
Mk 5:39-41—Jésù ní agbára láti jí àwọn tó ń “sùn” nínú ikú dìde (“kò tíì kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 5:39, nwtsty)
Mk 5:42—Àjíǹde tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú máa mú ká ní ‘ayọ̀ tó pọ̀ jọjọ’ (jy 118 ¶6)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mk 5:19, 20—Kí nìdí tí ohun tí Jésù sọ nínú àwọn ẹsẹ yìí fi yàtọ̀ sí ohun tó sábà máa ń sọ tẹ́lẹ̀? (“ròyìn fún wọn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 5:19, nwtsty)
Mk 6:11—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ẹ gbọn ìdọ̀tí tí ó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ yín dànù” túmọ̀ sí? (“ẹ gbọn ìdọ̀tí tí ó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ yín dànù” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mr 6:11, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mk 6:1-13
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fi ìkànnì jw.org han onílé.
Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti ìbéèrè fún ìgbà míì.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 36 ¶23-24—Fi béèyàn ṣe lè dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ hàn.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Máa Lo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́nà Tó Já Fáfá”: (5 min.) Ìjíròrò.
Bí Ètò Jèhófà Ṣe Tu Ìdílé Peras Nínú: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí ìdílé Peras ní? Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á? Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí nígbà tá a bá ń kojú ìdánwò?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí ¶1-9 àti àpótí “Bí Ẹ̀jẹ̀ Ṣe Lè Pa Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ́” àti “Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Àwọn Ẹranko Jọ Ẹ́ Lójú”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 72 àti Àdúrà