Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Lo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́nà Tó Já Fáfá

Máa Lo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́nà Tó Já Fáfá

Ńṣe ni iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn dà bí ìgbà téèyàn bá ń kọ́lé. Kí ilé náà lè dúró digbí, a gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń lo àwọn ohun èlò ìkọ́lé dáadáa. Ó ṣe pàtàkì ká mọ bá a ṣe lè lo olórí ohun tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2Ti 2:15) A tún gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe lè lo àwọn ìwé àti fídíò tó wà lára Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó já fáfá, ká lè sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. *

Báwo lo ṣe lè túbọ̀ mọ àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ lò dáadáa? (1) Ní kí alábòójútó àwùjọ yín ràn ẹ́ lọ́wọ́, (2) ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àkéde tó nírìírí tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé, kó o sì (3) máa ṣe ìdánrawò déédéé. Tó o bá ti ń mọ àwọn ìwé àtàwọn fídíò yìí lò dáadáa, ayọ̀ rẹ á túbọ̀ máa kún bó o ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tẹ̀mí tó ń lọ lọ́wọ́ yìí.

ÌWÉ ÌRÒYÌN

ÌWÉ PẸLẸBẸ

ÌWÉ ŃLÁ

ÀṢÀRÒ KÚKÚRÚ

FÍDÍÒ

ÌWÉ ÌKÉSÍNI

KÁÀDÌ ÌKÀNNÌ

^ ìpínrọ̀ 3 A dìídì ṣe àwọn ìtẹ̀jáde kan tí kò sí lárá Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn kan ní pàtàkì. A lè lo èyíkéyìí lára wọn nígbà tó bá yẹ.