April 9-15
MÁTÍÙ 27-28
Orin 69 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ Lọ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn—Kí Nìdí, Níbo àti Báwo?”: (10 min.)
Mt 28:18—Ọlá àṣẹ Jésù gbòòrò gan-an (w04 7/1 8 ¶4)
Mt 28:19—Jésù pàṣẹ pé ká máa wàásù kárí ayé, ká sì máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ (“sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn,” “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 28:19, nwtsty)
Mt 28:20—A gbọ́dọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù, kí wọ́n sì máa fi sílò (“ẹ máa kọ́ wọn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 28:20, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 27:51—Kí ni aṣọ ìkélé tó ya sí méjì dúró fún? (“ìkélé,” “ibùjọsìn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 27:51, nwtsty)
Mt 28:7—Báwo ni ańgẹ́lì Jèhófà ṣe buyì kún àwọn obìnrin tó wá síbi ibojì Jésù? (“sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ti gbé e dìde” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 28:7, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 27:38-54
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) g17.2 14—Àkòrí: Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Iṣẹ́ Ìwàásù àti Kíkọ́ni Ṣe Pàtàkì Láti Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn”: (15 min.) Ìjíròrò. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò kókó yìí, jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Máa Wàásù Nìṣó “Láìdábọ̀”—Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà àti Láti Ilé-Dé-Ilé àti Máa Wàásù Nìṣó “Láìdábọ̀”—Níbi Térò Pọ̀ Sí àti Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 6 ¶1-9
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 73 àti Àdúrà