Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

●○○NÍGBÀ ÀKỌ́KỌ́

Ìbéèrè: Ta ni Jésù?

Bíbélì: Mt 16:16

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Kí nìdí tí Jésù fi kú?

○●○ÌPADÀBẸ̀WÒ ÀKỌ́KỌ́

Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jésù fi kú?

Bíbélì: Mt 20:28

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bí Jésù ṣe kú fún wa?

○○●ÌPADÀBẸ̀WÒ KEJÌ

Ìbéèrè: Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bí Jésù ṣe kú fún wa?

Bíbélì: Jo 17:3

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Kí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa?

ÌKÉSÍNI SÍ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI (March 23–April 19):

A fẹ́ pè yín sí ìpàdé pàtàkì kan. Ìwé ìkésíni tiyín rèé. Ní Friday, April 19, ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé máa pé jọ láti ṣe ìrántí ikú Jésù Kristi. Ẹ máa rí àkókò àti ibi tá a ti máa ṣe ìpàdé náà nínú ìwé yìí. A tún fẹ́ kẹ́ ẹ wá gbọ́ àsọyé kan ní ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ìgbà yẹn, àkòrí rẹ̀ ni “Sapá Kó O Lè Ní Ìyè Tòótọ́!”

Tí Ẹni Náà Bá Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀ Rẹ, Fi Ìbéèrè Yìí Sílẹ̀: Kí nìdí tí Jésù fi kú?