April 1-7
1 KỌ́RÍŃTÌ 7-9
Orin 136 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ̀bùn Ni Wíwà Láìní Ọkọ Tàbí Aya”: (10 min.)
1Kọ 7:32—Ẹni tí kò ṣègbéyàwó lè sin Jèhófà láìsí àwọn àníyàn tí àwọn tọkọtaya máa ń ní (w11 1/15 18 ¶3)
1Kọ 7:33, 34—Àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó “máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti ayé” (w08 7/15 27 ¶1)
1Kọ 7:37, 38—Àwọn Kristẹni tí kò bá ṣègbéyàwó nítorí àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tí wọ́n ń lé, máa “ṣe dáadáa” ju àwọn tó ti ṣègbéyàwó lọ (w96 10/15 12-13 ¶14)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
1Kọ 7:11—Kí ló lè mú kí tọkọtaya Kristẹni kan sọ pé àwọn fẹ́ pínyà? (lv àfikún 219 ¶2-221 ¶3)
1Kọ 7:36—Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni “kọjá ìgbà ìtànná èwe” kí wọ́n tó ṣe ìgbéyàwó? (w00 7/15 31 ¶2)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 1Kọ 8:1-13 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni: (10 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ, lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ẹ̀kọ́ 4 nínú ìwé pẹlẹbẹ Kíkọ́ni.
Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w12 11/15 20—Àkòrí: Ṣé Àwọn Tó Yàn Láti Má Ṣe Ní Ọkọ Tàbí Aya Gba Ẹ̀bùn Yìí Lọ́nà Ìyanu? (th ẹ̀kọ́ 12)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
O Lè Fipò Àpọ́n Ẹ Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Ìṣòro wo ni àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó ń dojú kọ? (1Kọ 7:39) Kí la rí kọ́ lára ọmọbìnrin Jẹ́fútà? Kí ni Jèhófà máa ń fún àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́? (Sm 84:11) Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè fún àwọn tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó ní ìṣírí? Kí làwọn nǹkan tí ẹni tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó lè ṣe nínú ètò Ọlọ́run?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 4 ¶12-14 àti àfikún Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 42 àti Àdúrà