Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 10-13

Jèhófà Jẹ́ Olóòótọ́

Jèhófà Jẹ́ Olóòótọ́

10:13

Jèhófà lè yàn láti mú àdánwò kan kúrò; àmọ́, ó sábà máa ń “ṣe ọ̀nà àbáyọ” ní ti pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò ká lè fara dà á.

  • Jèhófà máa ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tó ń pèsè láti mú kí ọkàn wa balẹ̀, kára sì tù wá.​—Mt 24:45; Jo 14:​16, àlàyé ìsàlẹ̀; Ro 15:4

  • Ó lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa, èyí tó máa jẹ́ ká rántí àwọn àkọsílẹ̀ kan nínú Bíbélì tàbí àwọn ìlànà kan táá jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.​—Jo 14:26

  • Ó lè lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́.​—Heb 1:14

  • Ó lè lo àwọn ará wa láti ràn wá lọ́wọ́.​—Kol 4:11