Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Báwo Lo Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

Báwo Lo Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún yìí, a máa túbọ̀ ráyè múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi. Tí Ìrántí Ikú Kristi bá bọ́ sí àárín ọ̀sẹ̀, a ò ní ṣe Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní ọ̀sẹ̀ yẹn. Tí Ìrántí Ikú Kristi bá bọ́ sí òpin ọ̀sẹ̀, a ò ní ṣe ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀, ìyẹn àsọyé fún gbogbo ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ṣé wàá fi àsìkò tó ṣí sílẹ̀ yìí ṣe àwọn nǹkan tó yẹ? Bíi ti àwọn ará ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, a gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ètò kan láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi. (Lk 22:​7-13; km 3/15 1) Àmọ́, ó tún yẹ kí gbogbo wa múra ọkàn wa sílẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Ronú lórí ìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o wà níbẹ̀.​—1Kọ 11:​23-26

  • Ronú lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà tàdúràtàdúrà.​—1Kọ 11:​27-29; 2Kọ 13:5

  • Ka àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì ronú lé wọn lórí.​—Jo 3:16; 15:13

Àwọn akéde kan máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a máa ń kà nígbà Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n sì máa ń ronú lé e lórí, èyí tó máa ń wà nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Àwọn míì máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú àtẹ tó wà ní ìsàlẹ̀ yìí. Àwọn kan máa ń ka àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ìrántí Ikú Kristi àti ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní sí wa. Ètò èyíkéyìí tíwọ náà bá ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i, àdúrà wa ni pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.