ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI April 2020

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ìjíròrò tó dá lórí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún àwa èèyàn àti bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ.

Tuesday, April 7, 2020—Ìrántí Ikú Kristi

Báwo lo ṣe lè múra ọkàn rẹ sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jékọ́bù àti Lábánì Dá Májẹ̀mú Àlàáfíà

Báwo lo ṣe lè mú kí àlàáfíà wà nígbà tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àtàwọn míì?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ṣé Ò Ń Jìjàkadì Kó O Lè Gba Ìbùkún?

Ǹjẹ́ o múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè gba ìbùkún Ọlọ́run?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kí Ló Ṣe Pàtàkì Jù Sí Mi?

Kí ni ọwọ́ tá a fi mú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ń sọ nípa ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé wa?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àkóbá Tí Ẹgbẹ́ Búburú Máa Ń Fà

Kí ló máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá kó o bá ẹnì kan kẹ́gbẹ́ tàbí kó o má ṣe bẹ́ẹ̀?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

‘Ẹ Mú Àwọn Ọlọ́run Àjèjì Kúrò’

Báwo lo ṣe lè múnú Jèhófà dùn, kí sì lo lè ṣe káwọn ẹ̀mí èṣù má bàa nípa lórí rẹ?