Jékọ́bù àti Lábánì Dá Májẹ̀mú Àlàáfíà
Kí nìdí tí Jékọ́bù àti Lábánì fi fi òkúta ṣe òkìtì?
-
Ó jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn tó ń gbabẹ̀ kọjá pé àwọn méjèèjì jọ dá májẹ̀mú àlàáfíà
-
Ó ń rán wọn létí pé Jèhófà ń wò wọ́n kí wọ́n lè mú májẹ̀mú tí wọ́n dá náà ṣẹ
Lónìí, Jèhófà fẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Báwo ni àwọn nǹkan yìí ṣe lè mú kí àlàáfíà jọba nígbà tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín wa?
-
Ẹ jọ jókòó sọ ọ́.—Mt 5:23, 24
-
Ẹ dárí ji ara yín fàlàlà.—Kol 3:13
-
Ẹ mú sùúrù.—Ro 12:21