April 20-26
JẸ́NẸ́SÍSÌ 32-33
Orin 21 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ṣé Ò Ń Jìjàkadì Kó O Lè Gba Ìbùkún?”: (10 min.)
Jẹ 32:24—Jékọ́bù bá áńgẹ́lì kan jìjàkadì (w03 8/15 25 ¶3)
Jẹ 32:25, 26—Jékọ́bù ò juwọ́ sílẹ̀ títí tó fi rí ìbùkún gbà (it-2 190)
Jẹ 32:27, 28—Ọlọ́run bù kún Jékọ́bù torí pé ó forí tì í (it-1 1228)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 32:11, 13-15—Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jékọ́bù láti máa wá àlàáfíà? (w10 6/15 22 ¶10-11)
Jẹ 33:20—Kí nìdí tí Jékọ́bù fi pe pẹpẹ tó mọ yìí ní “Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì”? (it-1 980)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 32:1-21 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni Ẹ̀bùn ṣe lo àwọn ẹ̀rí tó péye tó sì ń yíni lérò pa dà? Kí ló fi hàn pé Ẹ̀bùn àti Ṣeun ti jọ múra ohun tí wọ́n fẹ́ sọ sílẹ̀?
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 12)
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 16)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Kí Ló Ṣe Pàtàkì Jù Sí Mi?”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Jẹ́ Kí Àwọn Àfojúsùn Tẹ̀mí Wà Lọ́kàn Rẹ Digbí.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 18 ¶8-13
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 150 àti Àdúrà