Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 32-33

Ṣé Ò Ń Jìjàkadì Kó O Lè Gba Ìbùkún?

Ṣé Ò Ń Jìjàkadì Kó O Lè Gba Ìbùkún?

32:24-28

Kí Jèhófà lè bù kún wa, a gbọ́dọ̀ sapá láti máa fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ láyé wa. (1Kọ 9:26, 27) Nígbà táwa náà bá ń ṣe ohun tó ní ín ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà, ó yẹ ká ní irú ẹ̀mí tí Jékọ́bù ní. A lè fi hàn pé à ń fi taratara wá ìbùkún Jèhófà tá a bá ń . . .

  • Múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa

  • Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé

  • Ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ

Ipò yòówù kó o wà, máa gbàdúrà déédéé sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó sì bù kún ìsapá rẹ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí n máa ṣe láti túbọ̀ máa fìtara wá ìbùkún Jèhófà?’