MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Ló Ṣe Pàtàkì Jù Sí Mi?
Jékọ́bù bá áńgẹ́lì jìjàkadì torí kó lè gba ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn ìbùkún Jèhófà. (Jẹ 32:24-31; Ho 12:3, 4) Àwa ńkọ́? Ṣé a ṣe tán láti fi gbogbo okun àti agbára wa ṣègbọràn sí Jèhófà, ká lè gba ìbùkún rẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, tí àsìkò ìpàdé bá forígbárí pẹ̀lú àsìkò tá a lè ṣe àfikún iṣẹ́, èwo la máa ṣe? Tá a bá ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa fún Jèhófà, ó máa ‘tú ìbùkún sórí wa títí a kò fi ní ṣaláìní ohunkóhun.’ (Mal 3:10) Á máa tọ́ wa sọ́nà, á máa dáàbò bò wá, á sì máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò.—Mt 6:33; Heb 13:5.
WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ ÀWỌN ÀFOJÚSÙN TẸ̀MÍ WÀ LỌ́KÀN RẸ DIGBÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo ni ohun tí arábìnrin yìí fẹ́ràn ṣe di ìdẹwò fún un?
-
Báwo ni iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa ṣe lè di ìdẹwò fún wa?
-
Kí nìdí tó fi yẹ kí Tímótì máa ní àfojúsùn tẹ̀mí kódà lẹ́yìn tí òtítọ́ ti jinlẹ̀ nínú rẹ̀?—1Ti 4:16
-
Báwo la ṣe lè fi hàn pé iṣẹ́ Ọlọ́run la kà sí pàtàkì jù?