Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 34-35

Àkóbá Tí Ẹgbẹ́ Búburú Máa Ń Fà

Àkóbá Tí Ẹgbẹ́ Búburú Máa Ń Fà

34:1, 2, 7, 25

Ó ṣeé ṣe káwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wa ní àwọn ìwà kan tó dáa, àmọ́ ṣéyẹn túmọ̀ sí pé a lè máa bá wọn kẹ́gbẹ́? Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ká bá ẹnì kan kẹ́gbẹ́ tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Ṣé ẹni yìí máa mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

  • Kí ni ọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ń dá lé, kí nìyẹn sì fi hàn pé ó ṣe pàtàkì sí i?​—Mt 12:34

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé àwọn tí mò ń bá rìn ń mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ni tàbí wọ́n mú kí n jìnnà sí i?’