MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
‘Ẹ Mú Àwọn Ọlọ́run Àjèjì Kúrò’
Jékọ́bù mọ̀ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa sìn, bó tílẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò tíì fún àwọn èèyàn ní òfin lórí ìbọ̀rìṣà. (Ẹk 20:3-5) Torí náà, nígbà tí Jèhófà ní kó pa dà sí Bẹ́tẹ́lì, Jékọ́bù pàṣẹ fún gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé kí wọ́n mú àwọn ère tó wà pẹ̀lú wọn kúrò. Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù kó gbogbo àwọn ère náà dànù títí kan yẹtí tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fi dáàbò bo ara wọn. (Jẹ 35:1-4) Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà máa dùn sí ohun tí Jékọ́bù ṣe.
Lóde òní ńkọ́, báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà nìkan ṣoṣo là ń sìn? Ohun pàtàkì tá a lè ṣe ni pé ká yẹra fún ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà tàbí ìbẹ́mìílò. Èyí gba pé ká kó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò dànù, ká sì ṣàyẹ̀wò eré ìnàjú tá à ń wò. Bí àpẹẹrẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn ìwé tàbí fíìmù tó dá lórí àwọn ẹlẹyẹ, àǹjọ̀nú, àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, babaláwo àtàwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn ni mo máa ń gbádùn? Ṣé àwọn fíìmù tí mò ń wò máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú idán pípa, èèdì tàbí ọfọ̀?’ A gbọ́dọ̀ ta kété sí ohunkóhun tí Jèhófà kórìíra.—Sm 97:10.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ DOJÚ ÌJÀ KỌ ÈṢÙ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Ìṣòro wo ni akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Palesa ní?
-
Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká wá ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà tó bá kan ọ̀rọ̀ ìbẹ́mìílò?
-
Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dáàbò bò wá, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká kó dànù?
-
Ìgbésẹ̀ akin wo ni Palesa gbé?
-
Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tó o bá fẹ́ yẹra fún ìbẹ́mìílò lágbègbè rẹ?