Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tuesday, April 7, 2020—Ìrántí Ikú Kristi

Tuesday, April 7, 2020​—Ìrántí Ikú Kristi

Tuesday, April 7, 2020—Ìrántí Ikú Kristi

Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni máa ṣàṣàrò lórí ọ̀nà tí Jèhófà àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ gbà fìfẹ́ tó gá jù lọ hàn sí wa. (Jo 3:16; 15:13) O lè lo àtẹ yìí láti ṣàyẹ̀wò ohun tàwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jésù ṣe kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù. Apá kẹfà nínú ìwé Jesus​—The Way, the Truth, the Life ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kí ló yẹ kí ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Kristi ní mú kó o ṣe?​—2Kọ 5:14, 15; 1Jo 4:16, 19.

IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ TÍ JÉSÙ ṢE KẸ́YÌN NÍ JERÚSÁLẸ́MÙ

Àkókò

Ibi

Ìṣẹ̀lẹ̀

Mátíù

Máàkù

Lúùkù

Jòhánù

33, Nísàn 8 (April 1-2, 2020)

Bẹ́tánì

Jésù dé lọ́jọ́ mẹ́fà ṣáájú Ìrékọjá

 

 

 

11:55–12:1

Nísàn 9 (April 2-3, 2020)

Bẹ́tánì

Màríà da òróró sí orí àti ẹsẹ̀ rẹ̀

26:6-13

14:3-9

 

12:2-11

Bẹ́tánì sí Bẹtifágè sí Jerúsálẹ́mù

Ó wọ Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

21:1-11, 14-17

11:1-11

19:29-44

12:12-19

Nísàn 10 (April 3-4, 2020)

Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù

Ó gégùn-ún fún igi ọ̀pọ̀tọ́; ó fọ tẹ́ńpìlì mọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i

21:18, 19; 21:12, 13

11:12-17

19:45, 46

 

Jerúsálẹ́mù

Àwọn àlùfáà àgbà àtàwọn akọ̀wé òfin gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù

 

11:18, 19

19:47, 48

 

Jèhófà sọ̀rọ̀; Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀; àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ nípa àìnígbàgbọ́ àwọn Júù ṣẹ

 

 

 

12:20-50

Nísàn 11 (April 4-5, 2020)

Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù

Ẹ̀kọ́ látara igi ọ̀pọ̀tọ́ tó rọ

21:19-22

11:20-25

 

 

Jerúsálẹ́mù, tẹ́ńpìlì

Wọ́n béèrè ẹni tó fún Jésù láṣẹ; àpèjúwe ọmọkùnrin méjì

21:23-32

11:27-33

20:1-8

 

Àwọn àpèjúwe: àwọn tó ń dáko tí wọ́n jẹ́ apààyàn, àsè ìgbéyàwó

21:33–22:14

12:1-12

20:9-19

 

Ó dáhùn ìbéèrè nípa Ọlọ́run àti Késárì, àjíǹde, àṣẹ tó tóbi jù lọ

22:15-40

12:13-34

20:20-40

 

Ó bi àwọn èrò bóyá Kristi jẹ́ ọmọ Dáfídì

22:41-46

12:35-37

20:41-44

 

Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí gbé

23:1-39

12:38-40

20:45-47

 

Ó kíyè sí ohun tí opó kan fi ṣètọrẹ

 

12:41-44

21:1-4

 

Òkè Ólífì

Ó sọ àmì ìgbà tí òun máa wà níhìn-ín

24:1-51

13:1-37

21:5-38

 

Àwọn àpèjúwe: wúńdíá mẹ́wàá, tálẹ́ńtì, àgùntàn àti ewúrẹ́

25:1-46

 

 

 

Nísàn 12 (April 5-6, 2020)

Jerúsálẹ́mù

Àwọn aṣáájú Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á

26:1-5

14:1, 2

22:1, 2

 

Júdásì ṣètò bó ṣe máa fà á lé wọn lọ́wọ́

26:14-16

14:10, 11

22:3-6

 

Nísàn 13 (April 6-7, 2020)

Nítòsí àti nínú Jerúsálẹ́mù

Ó múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá tó ṣe kẹ́yìn

26:17-19

14:12-16

22:7-13

 

Nísàn 14 (April 7-8, 2020)

Jerúsálẹ́mù

Ó bá àwọn àpọ́sítélì jẹ Ìrékọjá

26:20, 21

14:17, 18

22:14-18

 

Ó fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì

 

 

 

13:1-20

Jésù fi hàn pé Júdásì ni ọ̀dàlẹ̀, ó sì ní kó máa lọ

26:21-25

14:18-21

22:21-23

13:21-30

Ó dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ (1Kọ 11:​23-25)

26:26-29

14:22-25

22:19, 20, 24-30

 

Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun àti pé àwọn àpọ́sítélì máa fọ́n ká

26:31-35

14:27-31

22:31-38

13:31-38

Ó ṣèlérí olùrànlọ́wọ́; àpèjúwe àjàrà tòótọ́; ó pàṣẹ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn; àdúrà tó gbà kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì

 

 

 

14:1–17:26

Gẹ́tísémánì

Ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ọgbà; Júdásì fi Jésù hàn, wọ́n sì mú Jésù

26:30, 36-56

14:26, 32-52

22:39-53

18:1-12

Jerúsálẹ́mù

Ánásì bi Jésù léèrè ọ̀rọ̀; ìgbẹ́jọ́ níwájú Káyáfà, Sàhẹ́ndìrìn; Pétérù sẹ́ Jésù

26:57–27:1

14:53–15:1

22:54-71

18:13-27

Júdásì ọ̀dàlẹ̀ pokùn so (Iṣe 1:18, 19)

27:3-10

 

 

 

Níwájú Pílátù, lẹ́yìn náà Hẹ́rọ́dù, ó tún pa dà sọ́dọ̀ Pílátù

27:2, 11-14

15:1-5

23:1-12

18:28-38

Pílátù wá bó ṣe máa dá a sílẹ̀ àmọ́ àwọn Júù ní kó dá Bárábà sílẹ̀; wọ́n dájọ́ ikú fún un pé kí wọ́n kàn án mọ́ òpó igi oró

27:15-30

15:6-19

23:13-25

18:39–19:16

(n. aago mẹ́ta ọ̀sán)

Gọ́gọ́tà

Ó kú lórí òpó igi oró

27:31-56

15:20-41

23:26-49

19:16-30

Jerúsálẹ́mù

Wọ́n gbé òkú rẹ̀ kúrò lórí òpó igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì

27:57-61

15:42-47

23:50-56

19:31-42

Nísàn 15 (April 8-9, 2020)

Jerúsálẹ́mù

Àwọn àlùfáà àtàwọn Farisí gba àwọn ẹ̀ṣọ́ láti máa ṣọ́ ibojì náà, wọ́n sì sé e pa

27:62-66

 

 

 

Nísàn 16 (April 9-10, 2020)

Jerúsálẹ́mù àti agbègbè rẹ̀; Ẹ́máọ́sì

Jésù jíǹde; ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ẹ̀ẹ̀marùn-ún

28:1-15

16:1-8

24:1-49

20:1-25

Lẹ́yìn Nísàn 16

Jerúsálẹ́mù; Gálílì

Ó tún fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn (1Kọ 15:5-7; Iṣe 1:3-8); ó fún wọn ní ìtọ́ni; ó ní kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn

28:16-20

 

 

20:26–21:25