Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
JÍ!
Béèrè ìbéèrè: Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè jáwọ́ nínú àṣà tí kò dáa tó ti mọ́ni lára, kéèyàn sí fi èyí tó dáa rọ́pò rẹ̀, àmọ́ ṣé ó lérè?
Ka Bíbélì: Onw 7:8a
Fi ìwé lọni: Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àṣà tí kò dáa fún ire ara wa.
JÍ!
Béèrè ìbéèrè: Àwọn àyípadà kan gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa. Àmọ́, kí lẹ rò pé a lè ṣe tí àwọn àyípadà yẹn á fi bá wa lára mu?
Ka Bíbélì: Onw 7:10
Fi ìwé lọni: [Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 10 hàn án.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ tí àyípadà náà á fi bá wa lára mu.
TẸ́TÍ SÍ ỌLỌ́RUN KÓ O LÈ WÀ LÁÀYÈ TÍTÍ LÁÉ
Béèrè ìbéèrè: Gbogbo wa pátá la ní orúkọ, tó fi mọ́ àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa. Ǹjẹ́ ẹ tiẹ̀ rò pé Ọlọ́run ní orúkọ?
Ka Bíbélì: Sm 83:18
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn nǹkan míì tí Bíbélì fi kọ́ wa nípa Ọlọ́run. [Fi ohun tó wà lójú ìwé 6 àti 7 hàn án.]
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.