August 1 Sí 7
SÁÀMÙ 87-91
Orin 49 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Má Ṣe Kúrò Ní Ibi Ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ”: (10 min.)
Sm 91:
1, 2 —“Ibi ìkọ̀kọ̀” Jèhófà ń pèsè ààbò fún wa nípa tẹ̀mí (w10 2/15 ojú ìwé 26 àti 27 ìpínrọ̀ 10 àti 11) Sm 91:3
—Bíi ti pẹyẹpẹyẹ, Sátánì fẹ́ dẹ pańpẹ́ mú wa (w07 10/1 ojú ìwé 26 sí 30 ìpínrọ̀ 1 sí 18) Sm 91:
9-14 —Jèhófà ni ààbò wa (w10 1/15 ojú ìwé 10 àti 11 ìpínrọ̀ 13 àti 14; w01 11/15 ojú ìwé 19 àti 20 ìpínrọ̀ 13 sí 19)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 89:
34-37 —Májẹ̀mú wo ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí, báwo sì ni Jèhófà ṣe ṣàpẹẹrẹ bó ṣe jóòótọ́ tó? (w14 10/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 14; w07 7/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 3 àti 4) Sm 90:
10, 12 —Báwo ni a ṣe ń ‘ka àwọn ọjọ́ wa lọ́nà tí a ó fi ní ọkàn-àyà ọgbọ́n’? (w06 7/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 4; w01 11/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 19) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 90:
1-17
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ: (5 min.)
“Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I
—Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣe Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi”: (10 min.) Ìjíròrò. Lo àwọn ìbéèrè yìí láti fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó ti ran ẹnì kan lọ́wọ́ débi pé onítọ̀hún ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Báwo lẹ ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ yín lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Báwo lẹ ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ yín lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 21 ìpínrọ̀ 1 sí 12
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 137 àti Àdúrà