Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣe Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣe Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tó lè rí ojúure Jèhófà, wọ́n ní láti ṣe ìyàsímímọ́ kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. (1Pe 3:21) Lẹ́yìn ìyẹn, ààbò tẹ̀mí máa wà fún àwọn tó bá gbé ìgbé ayé tó bá ìyàsímímọ́ wọn mú. (Sm 91:1, 2) Jèhófà ni Kristẹni kan máa ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún kì í ṣe sí ẹnikẹ́ni, iṣẹ́ tàbí àjọ èyíkéyìí. Torí náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì mọ rírì rẹ̀.Ro 14:7, 8.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ẹ jíròrò ohun tí ẹ̀kọ́ náà ń sọ nípa Jèhófà. Tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kó máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó sì máa gbàdúrà sí Jèhófà “láìdabọ̀.”1Tẹ 5:17; Jak 4:8

  • Gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó fi ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ṣe àwọn àfojúsùn rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Bákan náà, ràn án lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn kan, bíi kó máa dáhùn láwọn ìpàdé, kó máa wàásù fún àwọn aládùúgbò rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Má gbàgbé pé Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti sin òun, torí náà, ẹni náà ló máa pinnu bóyá kí òun ṣe ìyàsímímọ́ tàbí kí òun má ṣe.Di 30:19, 20

  • Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tó bá yẹ kó lè múnú Jèhófà dùn, kó sì tóótun láti ṣèrìbọmi. (Owe 27:11) Torí pé àwọn ìwà kan tàbí àṣà kan wà tí kì í tán lára bọ̀rọ̀, akẹ́kọ̀ọ́ kan lè nílò ìrànlọ́wọ́ àtìgbàdégbà kó lè bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ kí ó sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. (Ef 4:22-24) Ẹ jíròrò ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó máa ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tó ní àkòrí náà, “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà”

  • Sọ àwọn ìrírí tó ń fún ẹ láyọ̀ tó o ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún un.Ais 48:17, 18