MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àkànṣe Ìwàásù Láti Pín Ìwé Ìròyìn Ilé Ìṣọ́ Lóṣù September
Gbogbo èèyàn tó wà láyé ló nílò ìtùnú. (Onw 4:1) Lóṣù September, a máa pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lákànṣe, àkòrí Ilé Ìṣọ́ yẹn máa dá lorí ìtùnú. Ẹ rí ì dájú pé ẹ pín ìwé ìròyìn yìí fún gbogbo èèyàn. Ká tó lè tù àwọn èèyàn nínú, a ní láti rí wọn ká sì bá wọn sọ̀rọ̀, torí náà, a ò ní fí ìwé ìròyìn yìí sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé.
OHUN TÁ A LÈ SỌ
“Gbogbo wa la máa ń nílò ìtùnú lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n ibo lẹ rò pé a ti lè rí ìtùnú? [Ka 2 Kọ́ríńtì 1:
Bí ẹni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa tó sì gba ìwé ìròyìn náà, . . .
FI FÍDÍÒ KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ? HÀN ÁN
Lẹ́yìn náà, fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́.
MÚRA RẸ̀ SÍLẸ̀ DE ÌGBÀ TÓ O MÁA PA DÀ WÁ
Bi í ní ìbéèrè tí wàá dáhùn nígbà tó o bá pa dà wá, irú bíi “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?”