Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa fi Òtítọ́ Kọ́ni

Máa fi Òtítọ́ Kọ́ni

Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tuntun kan á máa jáde nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, àkòrí rẹ̀ ni “Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni.” A fẹ́ ká máa fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tuntun yìí wàásù òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn, ò máa jẹ́ lọ́nà ìbéèrè, lẹ́yìn náà, a máa fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tì í lẹ́yìn.

Tá a bá rí i pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, a lè fún un ní ìtẹ̀jáde èyíkéyìí tàbí ká fi ọ̀kan lára àwọn fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo hàn án, èyí á jẹ́ kó lè máa fojú sọ́nà fún ìgbà míì tá a máa pa dà wá. Ẹ jẹ́ ká tètè pa dà lọ bẹ̀ ẹni náà wò láàárín ọjọ́ díẹ̀ ká lè máa bá ìjíròrò wa nìṣó. Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tuntun yìí àti iṣẹ́ tá a yàn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa dá lórí àwọn ohun tó wà nínú orí kọ̀ọ̀kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ Wa? lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì wà níbẹ̀ tó máa jẹ́ ká lè lo Bíbélì nìkan nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ọ̀nà kan ṣoṣo ló lọ sí ìyè. (Mt 7:13, 14) Onírúurú àwọn èèyàn tó wà láti ibi tó wá yàtọ̀ síra là ń wàásù fún, ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ń ṣe, torí náà, àwọn òtítọ́ Bíbélì tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa nífẹ̀ẹ́ sí ló yẹ ká bá wọn sọ. (1Ti 2:4) Bá a ṣe ń fi onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn, ayọ̀ wa á máa pọ̀ sí i, a ó túbọ̀ jáfáfá nínú bí a ṣe ń “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́,” ìyẹn sì máa jẹ́ ká kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́.2Ti 2:15.