ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI August 2018
Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
Oríṣiríṣi ọ̀nà tá a lè gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí Bíbélì ṣe wúlò tó lóde òní.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Máa Dúpẹ́ Oore
Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ ṣe ohun tó wu Kristi gbọ́dọ̀ máa fi ìfẹ́ àti ìmọrírì hàn sáwọn míì, láìka orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn wọn sí.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì
Báwo làwa náà ò ṣe ní pàdánù ojú rere Ọlọ́run bíi ti aya Lọ́ọ̀tì? Kí la lè ṣe tá a bá fura pé kíkó ohun ìní jọ ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá
Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa mínà mẹ́wàá, kí ni ọ̀gá náà, àwọn ẹrú, àti owó yẹn ṣàpẹẹrẹ?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG
Gbogbo ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ ló ń darí àwọn èèyàn sí ìkànnì jw.org. Tá a bá mọ bá a ṣe lè lo ìkànnì náà, ó máa jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ sèso rere.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”
Jésù máa tó wá ṣèdájọ́ àwọn ẹni ibi, á sì gba àwọn olóòótọ́ là. A gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí, ká bàa lè rí ìgbàlà.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ṣe Tán Láti Dárí Jini
Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ máa ń kíyè sí ọkàn ẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀ tó sì wá yí pa dà, kí wọ́n lè dárí jì í.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ́ KRISTẸNI
Jésù Kú fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Náà
Jésù fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún àwa èèyàn aláìpé. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìpé bíi tiwa?