MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Gbogbo ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ ló ń darí àwọn èèyàn sí ìkànnì jw.org. Olórí ìdí tá a fi ṣe káàdì ìkànnì jw.org àti ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé? ni láti darí àwọn èèyàn sí ìkànnì wa. O lè lo ìkànnì jw.org láti fún àwọn èèyàn láwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é ni pé ká fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí wọ́n fi ń gba lẹ́tà lórí Kọ̀ǹpútà tàbí ká fi ìlujá ránṣẹ́, èyí sì máa gbéṣẹ́ nígbà tá a bá ń wàásù fún ẹnì kan tí kò gbọ́ èdè wa. Láfikún sí i, àwọn èèyàn lè béèrè àwọn ìbéèrè tí kò sí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́. Tá a bá mọ bá a ṣe lè lo ìkànnì náà, ó máa jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ sèso rere.
BÁ A ṢE LÈ LO:
-
Abala “Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ”. Ká sọ pé ò ń wàásù fún òbí kan tó fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọmọ títọ́. Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌGBÉYÀWÓ ÀTI ÌDÍLÉ.
-
Abala “ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE”. Ká sọ pé ò ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà níléèwé, tó o sì fẹ́ jíròrò ohun tó wà nínú ìwé Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè pẹ̀lú ọmọ iléèwé rẹ. Lọ sí ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ.
-
Abala “NÍPA WA”. Ká sọ pé ò ń wàásù fún ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, tẹ́ni náà sì fẹ́ ìsọfúnni sí i nípa ohun tá a gbà gbọ́. Lọ sí NÍPA WA > ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ.
WO FÍDÍÒ NÁÀ BÁ A ṢE LÈ LO ÌKÀNNÌ JW.ORG, LẸ́YÌN NÁÀ WÁ IBI TÓ O LÈ LỌ LÁTI ṢÈRÀNWỌ́ FÚN:
-
ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà
-
ẹni tí àjálù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí
-
arákùnrin tàbí arábìnrin tó ti di aláìṣiṣẹ́ mọ́
-
ẹni tí a ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, àmọ́ tó fẹ́ mọ bá a ṣe ń rówó ṣe iṣẹ́ ìwàásù
-
ẹni tó wá láti orílẹ̀-èdè míì, tó sì fẹ́ mọ ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní orílẹ̀-èdè rẹ̀