Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá
Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn apá tó wà nínú àpèjúwe náà dúró fún?
-
Ọ̀gá náà ṣàpẹẹrẹ Jésù
-
Àwọn ẹrú yẹn ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù
-
Owó tí ọ̀gá náà gbé fún àwọn ẹrú rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn, tó jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì
Àpèjúwe yìí jẹ́ ìkìlọ̀ tó jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi bá lọ ní irú ìwà tí ẹrú burúkú yẹn ní. Jésù retí pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lo ohun ìní wọn lẹ́nu iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.
Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lẹ́nu iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?