MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jésù Kú fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Náà
Jésù fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún àwa èèyàn aláìpé. (Ro 5:8) Abájọ tí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi mọ rírì ìfẹ́ tí Jésù fi hàn nípa bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ ni Kristi kú fún. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìpé bíi tiwa? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, a lè yan àwọn míì lọ́rẹ̀ẹ́, irú bíi àwọn tí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ wọn dàgbà yàtọ̀ sí tiwa. (Ro 15:7; 2Kọ 6:12, 13) Ìkejì ni pé, ó yẹ ká máa ṣọ́ra ká má bàa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó máa bí àwọn míì nínú. (Ro 14:13-15) Ní paríparí ẹ̀, tí àwọn míì bá ṣẹ̀ wá, ó yẹ ká máa tètè dárí jì wọ́n. (Lk 17:3, 4; 23:34) Tá a bá sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní àwọn ọ̀nà yìí, Jèhófà máa jẹ́ kí ìjọ wà ní ìṣọ̀kan àti ní àlááfíà.
WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA SUNWỌ̀N SÍ I LÓJOOJÚMỌ́! KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ: