MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì
Kí nìdí tí aya Lọ́ọ̀tì fi bojú wẹ̀yìn bó ṣe ń sá kúrò nílùú Sódómù? Bíbélì ò sọ ìdí. (Jẹ 19:17, 26) Ìkìlọ̀ tí Jésù ṣe fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ̀ má kúrò nínú àwọn nǹkan tó fi sílẹ̀. (Lk 17:31, 32) Báwo làwa náà ò ṣe ní pàdánù ojú rere Ọlọ́run bíi ti aya Lọ́ọ̀tì? A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí eré bá a ṣe máa kó àwọn ohun amáyédẹrùn jọ gbà wá lọ́kàn. (Mt 6:33) Jésù kọ́ wa pé a “kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mt 6:24) Àmọ́, kí la lè ṣe tá a bá fura pé kíkó ohun ìní jọ ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́? A lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n láti rí àwọn ibi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe, ká sì nígboyà àti okun láti ṣe bẹ́ẹ̀.
ṢÓ O RÁNTÍ FÍDÍÒ ALÁPÁ MẸ́TA NÁÀ Ẹ RÁNTÍ AYA LỌ́Ọ̀TÌ? Ó YÁ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo ni bí wọ́n ṣe ń fúngun mọ́ Gloria láti túbọ̀ kó owó jọ ṣe kó bá bó ṣe ń ronú, bó ṣe ń sọ̀rọ̀, àti ìwà rẹ̀?
-
Báwo ni aya Lọ́ọ̀tì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ ká yẹra fún lónìí?
-
Báwo ni ìlànà Bíbélì tí Joe àti ìdílé rẹ̀ fi sílò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
-
Báwo làwọn tí Anna ń bá kẹ́gbẹ́ ní ibiṣẹ́ ṣe ṣàkóbá fún un nípa tẹ̀mí?
-
Kí nìdí tá a fi nílò ìgboyà nígbà tí wọ́n bá ń fúngun mọ́ wa pé ká wá bá a ṣe máa rí towó ṣe?
-
Báwo ni Brian àti Gloria ṣe pa dà fi àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà sípò àkọ́kọ́?
-
Ìlànà Bíbélì wo lo rí nínú fídíò yìí?