MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ “Ní Ìtara fún Iṣẹ́ Rere”
Nínú lẹ́tà onímìísí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Títù, ó sọ pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin irú bí Títù máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti “jẹ́ àpẹẹrẹ nínú àwọn iṣẹ́ rere.” (Tit 2:6, 7) Nínú orí Bíbélì yẹn kan náà, ó sọ pé Jésù máa wẹ àwọn èèyàn Jèhófà mọ́, kí wọ́n lè “ní ìtara fún iṣẹ́ rere.” (Tit 2:14) Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ rere yẹn ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti kíkọ́ni. Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ẹ́, ṣé ìwọ náà lè lo okun tó o ní láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé?—Owe 20:29.
Tó o bá fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ṣètò ara rẹ kíwọ náà lè di aṣáájú-ọ̀nà. (Lk 14:28-30) Bí àpẹẹrẹ, báwo lo ṣe máa rówó bójú tó ara rẹ ní gbogbo ìgbà tó o fi ń ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún yìí? Báwo ni wàá ṣe dójú ìlà wákàtí tá a béèrè fún? Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm 37:5) Sọ ohun tó o fẹ́ ṣe fún àwọn òbí rẹ àtàwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, kó o gbé ìgbésẹ̀, kí àwọn àfojúsùn rẹ lè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀!
WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ TÓ Ń YIN JÈHÓFÀ, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Àwọn ìṣòro wo làwọn aṣáájú-ọ̀nà kan ti borí, báwo sì ni wọ́n ṣe ṣeé?
-
Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé?
-
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn ní ètò fún iṣẹ́ ìwàásù?
-
Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà níṣìírí, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́?
-
Ìbùkún wo làwọn tó ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà máa ń rí?