Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
JÍ!
Béèrè ìbéèrè: Gbogbo wa ló máa ń wù pé ká ní ìlera tó dáa. Kí lẹ rò pé a lè ṣe ká má báa máa ṣàìsàn ní gbogbo ìgbà?
Ka Bíbélì: Owe 22:3
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ onírúurú nǹkan tá a lè ṣe tí a ò fi ní máa ṣàìsàn ní gbogbo ìgbà.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
Béèrè ìbéèrè: Ṣé Ọlọ́run ló ń fa ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, àbí nǹkan míì ló ń fà á?
Ka Bíbélì: Job 34:10
Òtítọ́: Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Èṣù ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá, ó sì tún lè jẹ́ àfọwọ́fà àwọn èèyàn, tàbí kéèyàn ṣe kòńgẹ́ aburú. Tá a bá ń jìyà, Ọlọ́run wà níbẹ̀ fún wa láti ràn wá lọ́wọ́, torí pé ó bìkítà fún wa.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ? (Fídíò)
Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ ẹ rò pé Ọlọ́run ló ń darí ayé yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí lè yà yín lẹ́nu. Fídíò kékeré yìí sọ díẹ̀ lára wọn. [Jẹ́ kó wo fídíò náà.]
Fi ìwé lọni: Orí 11 nínú ìwé yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run kò tíì fi mú ìyà tó ń jẹ wá kúrò, ó sì tún ṣàlàyé ohun tó máa ṣe nípa rẹ̀. [Fún un ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.]
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.