Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Èmi Nìyí! Rán Mi!”

“Èmi Nìyí! Rán Mi!”

Aísáyà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa, torí pé ó múra tán láti jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. Ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́, torí pé kíá ló yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kó mọ gbogbo ohun tó rọ̀ mọ́ ọn. (Ais 6:8) Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ṣe àwọn àyípadà kan kó o lè lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i? (Sm 110:3) Àmọ́ kó o tó lọ, ó ṣe pàtàkì pé kó o “gbéṣirò lé ìnáwó náà.” (Lk 14:27, 28) Síbẹ̀, ó dáa kó o múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan nítorí iṣẹ́ ìwàásù. (Mt 8:20; Mk 10:28-30) Bá a ṣe rí i nínú fídíò tá a pé àkọlé rẹ̀ ní A Kó Lọ Síbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I, àwọn ìbùkún tí à ń rí gbà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kọjá ohunkóhun tá a lè yááfì.

LẸ́YÌN TÓ O BÁ TI WO FÍDÍÒ NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn nǹkan wo ni ìdílé Arákùnrin Williams yááfì kí wọ́n lè lọ sìn lórílẹ̀-èdè Ecuador?

  • Kí làwọn nǹkan tí wọ́n gbé yẹ̀wò kí wọ́n tó yan ibi tí wọ́n máa lọ?

  • Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n rí gbà?

  • Ibo lo ti lè rí ìsọfúnni nípa lílọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i?

NÍGBÀ ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ YÍN TÓ KÀN, Ẹ JÍRÒRÒ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo la ṣe lè mú iṣẹ́ ìsìn wa gbòòrò sí i nínú ìdílé wa? (km 11/11 ojú ìwé 5 sí 7)

  • Tí a ò bá lè lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà ran ìjọ wa lọ́wọ́? (w16.03 ojú ìwé 3 sí 5)