Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Tó Ní Ìmúṣẹ
Ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó bí Jésù, wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa wàásù ní “ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí Jésù lára, ní ti pé ó rìnrìn àjò jákèjádò Gálílì ó ń wàásù ó sì ń kọ́ni ní ìhìn rere.
-
Ó ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́
—Jo 2:1-11 (Kánà) -
Ó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀
—Mk 3:13, 14 (nítòsí Kápánáúmù) -
Ó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè
—Mt 5:1–7:27 (nítòsí Kápánáúmù) -
Ó jí ọmọ opó kan dìde
—Lu 7:11-17 (Náínì) -
Ó fara han nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tó jíǹde
—1Kọ 15:6 (Gálílì)